Inu ede ti a ti n ya oro lo.
Ona ti a n gba ya oro wonu ede Yoruba.
Akoonu
Oro – ayalo -: ni awon oro ajeji ti a maa n ya wonu ede Yoruba lati inu ede miiran
Oro – ayalo -: ni mimu oro lati inu ede kan wo inu ede miiran lona ti pipe ati kiko re yoo fi wa ni ibamu pelu ede ti a mu-un wo.
Oro – ayalo maa n mu ki ede dagba.
Bakan naa, o maa n je ki oruko wa fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba n sese n wo awujo wa
Yoruba ni ilana meji ti won n gba ya oro wo inu ede Yoruba, awon naa ni
– Ilana afetiya
– ilana afojuya
Ilana afetiya -: eyi ni pipe oro ayalo ni ona to sunmo bi awon elede se n pe oro gan-an
Bible – Baibu
Peter – Pita
Table – Tebu
Esther – Esita
Deacon – Dikin
Council – kansu
Al- basal – alubosa
Ilana afojuya :- eyi ni kiko oro ni liana eyi to sunmo bi awon elede se n ko.awon elede se n saaba maa n lo ilana yii
Soldier – soja
Table – tabili
Peter – peteru
Esther – esiteri
Bible – Bibeli
Deacon – Diakoni
Paradise – paradise
Hebrew – Heberu
Inu awon ede wonyii ni a ti n ya oro wo inu ede Yoruba
Ede Geesi
Ede Larubawa
Ede Faranse
Bi oro ayalo se wonu ede Yoruba
Eyi ni orisirisii ona ti oro ayalo gba wonu ede Yoruba
- Esin:- nipase esin musulumi ati esin Kristi ti won mu wa fun wa ni a se ni awon oro wonyi: mosalasi, soosi, alijanna, angeli bibeli, pasito, kurani abbl
- Ajose owo:- eyi ni ajose owo laarin Yoruba ati awon eya miiran ap: senji, korensi, wisiki, buluu
- Eto iselu:- Nipase ijoba ajeji ti awon larubawa ati Geesi mu wa ni a ti ya opolopo oro bii seria, kootu, sinato
- Asa ati olaju:- ajumose nipa asa ati olaju mu ki a ya opolopo oro lo ap: yigi, marede
- Eto eko:- eyi ni oro ti a ya nipa eto eko ap tisa, boodu,
AWON IRO TI A FI N SE AARO ARA WON
Ki oro ede Geesi ti a ya lo to le di ara oro mu ede Yoruba, o gbodo tele ofin ede Yoruba
- Konsonanti ki i gbeyin oro ninu ede Yoruba bi oro ayalo ba ni, a o fi faweli ti o ye seyin re, o le je: i, u a tabi o, ap
Bread – buredi
Gum – goomu
Bed – beedi
Shirt – seeti
fail – feeli
Glass – gilaasi
Gold – goolu
- Yiyo konsonanti ipari oro ayalo kuro ap
Mobil – mobi
Moses – mose
Jesus – jesu
Lazarus – lasaru
iii. Yiya isupo konsonanti oro- ayalo fifi faweli ya isupo konsonanti ap
bread – buredi
milk – miliiki
iray – Tiree
station – Tesan
belt – beliiti
- Ifiropo konsonanti ninu oro ayalo Nigba miirran konsonanti oro Geesi maa n yato si ti Yoruba ap:
Lazarus – lasaru
Church – soosi
Queen – kun-yin
Valve – faafu
Stamp – sitanbu
Cup – koobu
- Ami gbodo wa lori oro- ayalo
- Oro ayalo lo maa n bere pelu ami ohun oke
- Faweli aranmupe maa n bere oro ayalo
- Iwulo oro ayalo
- Oro ayalo lo maa n mu ki edi dagba
- Nipa yiya oro lo a maa n ri oruko fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba sese n wo awujo wa.
Ofin ti o de oro ayalo
IGBELEWON
- Kin ni oro-ayalo?
Ona meloo ni a n gba lati ya oro lo? Salaye won pelu apeere
IWE AKATILEWA
Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.
ASA
AWON ISERUN ENI
Akoonu
Awon iserun eni tumo si baba-nla eni, ti o se iran eni sile tabi ori eni ti iran kan ti bere. Ko si iran kan ni ile Yoruba ti ko ni awon ti o see nitori pe ‘okun ki i gun titi ki o ma ni ibi ti o ti fa wa.
Awon baba-nla wa ti a n toka si yii ti wa nigba iwase, won ti se gudugudu meje ohun yaaya mefa nigba aye won.
Awon Yoruba gbagbo pe odo ki san ki o gbagbe orisun re, opolopo igba ni won maa n pe oruko baba-nla fun iyonu ati aabo nitori pe won gbagbo pe eni to ba ti ku ni agbara nla lati bukun awon ti won je iran won ni aye.
Akoko odun tabi loorekoore ni a maa n se etutu lati tu awon iserun eni loju fun oore ti won n reti lodo won.
Odoodun ni awon iran miiran maa n bo iserun won tabi nigba ti wahala tabi idarudapo ba wa ninu ebi won.
Ebi kookan ni o ni ojubo ti won ti n bo iserun won, o le je agboole tabi ni eyin odi ilu. Iru eyin odi yii le je ibi ti baba-nla won tedo si nigba iwase.
Ogangan ibi ti oku ba kori si ni won ti n se etutu
Orisiirisii ohun jije mimu ni won n bo iserun eni, agbo tabi agutan adie abbl. Won yoo si ro eje re si oju oori iserun won naa, won yoo da obi, ti o ba si ti yan, o ti gba niyen, akoko ayeye ni o maa n je fun gbogbo ebi
Ni ile Ijebu Agemo ni won nse. Awon ni ipinle Eko kii fi Adamu – Orisa sere.
Ila oju, oriki –orile ati isesi iran kookan je eyi ti a fi n da ara wa mo, ti o si n mu iserun eni wa si iranti.
Inu oriki-orile ise, ise, iwa, esin, ati eewo iran ni a ti n gbo oniruuru oruko ti an baba-nla wa ti je seyin.
Ap
Iran onikoyi je iran jagun, eyi si han ninu oriki ati itan iran won, baba –nla won je jagunjagun.
Iwa akin hihu ko si fi iran yii sile. Iran aagberi ko fe gbagbe oogun abenu gongo.
Iran Olofa kan o je gbagbe ijakadi.
IGBELEWON
- Ki ni iserun eni tumo si?
- Daruko awon iserun ile Yoruba ti o mo.
IWE AKATILEWA
Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.
ETO EBI
Ni ile Yoruba, ebi ni a tun n pe ni alajobi tabi molebi. Alajobi ni iya, baba, egbon, aburo ati ibatan eni ni apapo. Eto ebi ni opomulero ti o gbe asa, ise, ati ibara-eni-gbepo awon Yoruba duro. omo nibi-niran ni awon Yoruba. Bi won se tan si ile baba ni won tan si ile iya.
Eto ebi bere lati inu ile. Gege bi asa baba ni olori ile, iya ni atele ki o kan awon omo gege bi ojo ori won. Iko kokan ni o ni ipa ti o n ko lati mu ki ife, isokan, laafia ati ajosepo wa ninu ebi.
Lara awon ibasepo ti o wa ninu ebi ni:
Ise obi si omo
Ise omo si obi.
Ibasepo laarin omo iya si omo iya
Ibasepo laarin Obakan si Obakan
Ibasepo laarin idile eni ati baba eni
Ipo Baale ati ojuse re
Ipo Iyaale Ile ati ise re
Ipo Obinrin ile
Ipo Orogun
Ipo Omo Osu ati ise won
Ipo Omokunrin Ile ati ise won
Ipo Omobinrin ile
Awon Alejo tabi Alabagbe
IGBELEWON
- Salaye awon wonyi: Obakan, Iyekan-eni, Omo Osu, Obinrin Ile ati Omobinrin Ile.
- Ki ni ojuse Baale Ile? Salaye ni kikun.
IWE AKATILEWA
Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.
LITIRESO
Kika iwe ti ajo WAEC yan
IGBELEWON
- a. Kin ni iserun eni?
- Igba wo ni a n bo iserun eni?
- Kin ni a fi n bo won?
IWE AKATILEWA
Imo Ede Asa ati Litireso Yoruba (SS3) S.Y Adewoyin 277 – 279
APAPO IGBELEWON
- Kin ni oro-ayalo?
- Ona meloo ni a n gba lati ya oro lo? Salaye won pelu apeere
- Salaye awon wonyi: Obakan, Iyekan-eni, Omo Osu, Obinrin Ile ati Omobinrin Ile.
- Ki ni ojuse Baale Ile? Salaye ni kikun.
ATUNYEWO EKO
- Ki ni oro oruko?
- Ki ni oro aropo oruko?
- Ko iyato merin laarin oro oruko ati oro aropo oruko.
ISE ASETILEWA
- Awon Iserun eni tumo si (a) Baba-nla eni (b) eni ti o se iran eni sile (d) eni to na omokunrin ile
- Inu _______ ni a ti n gbo nipa oniruuru oruko idile (a) oriki orile (b) iwure (d) ofo
- Ojubo iserun eni le wa ni _____ ati (a) Inui le (b)agboole (d) ilu odikeji
- Ona _____________ ni a le gba ya oro lo ninu ed Yoruba (a) meji (b) meta (d) merin
- A ya pasito ni pase _____(a) esin (b) eto eko (d) imo ero
APA KEJI
- Kin ni oro – ayalo?
- Ona meloo ni a n gba ya oro wonu ede Yoruba
- Ko irisi awon oro Geesi wonyi sile leyin igba ti a ba ti ya won wonu ede Yoruba
Teacher, Starch, Milk, bread, class, scale, block, trouser, brother, shilling
- Kin ni iserun eni
- Daruko apeere Iserun eni meta nile Yoruba
- Daruko igba ati ohun ti a si n bo iserun eni.
- Salaye eto ebi ni kikun.
See also
ASA ELEGBEJEGBE
AKOLE ISE: ISORI ORO NINU GBOLOHUN
AKOLE ISE: AROKO ATONISONA ALAPEJUWE