AKOLE ISE: ITESIWAJU LORI EKO IRO EDE YORUBA
Apejuwe iro faweli
A le sapejuwe iro faweli ni ona merin wonyi;
- Ipo ti afase wa
- Apa kan ara ahon to gbe soke ju lo ninu enu
- Bi apa to ga soke naa se ga to ninu enu
- Ipo ti ete wa
- Ipo ti afase wa: Afase le gbera soke di ona si imu la.
Iro faweli airanmupe ni a pe nigba ti afase gbe soke – a e e I o o u
Iro faweli aranmupe ni a pe nigba ti afase wa sile – an en in on un
- Ipo ahon: ti a ba pe faweli, apa kan ara ahon maa n gba soke ti yoo su ike mu eny. Bi apa
- Bi apa to ga soke naa se to ninu enu: Eyi ni iwon bi ahon se ga to ninu enu
- Ipo ete: Ipo meji ni ete maa n we ti a ba n pe iro faweli.
Ete le ri perese: Ti ete bari perese awon faweli ti a n pe jade ni, a e e I an en in
Ete le ri roboto: Ti ete ba ri roboto awon iro faweli ti a n pe jade ni, o, u, o, un, on
Apejuwe iro faweli airanmupe
- Faweli airanmupe ayanupe (odo), aarin, perese
e- Faweli airanmupe ahanu diepe (ebake) iwaju, perese
e- Faweli airanmupe ayanu diepe (ebado) iwaju, perese
- Faweli airanmupe hanupe (oke) iwaju, perese
o- Faweli airanmupe ahanu diepe (ebake) eyin roboto
o- Faweli airanmupe ayanu diepe (ebado) eyin roboto
u- Faweli airanmupe ahanupe (oke) eyin roboto
Apejuwe iro faweli aranmupe
An- Faweli aranmupe ayanupe (odo) aarin perese
En- Faweli aranmupe ayanu diepe (ebado) iwaju perese
In- Faweli aranmupe ahanupe (oke) iwaju perese
On- Faweli aranmupe ayanu diepe (ebado) eyin roboto
Un- Faweli aranmupe ahanupe (oke) eyin roboto
ATE FAWELI
Iwaju aarin eyin iwaju aarin eyin
Ahanupe i U in
Ahanupe un
Ahanudiepe e o
en on
Ayanudiepe e o Ayanudiepe an
Ayanupe a Ayanupe
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: OWE
Owe ni afo to kun fun imo ijinle ogbon ati iriir awon agba.
Owe lesin oro, oro lesin owe, bi oro ba sonu owe ni a fi n wa.
Awon agba n lo owe lati yaju oro to takoko.
Orisi owe
Isori marun-un ni a le pin owe Yoruba si. Awon niyi,
- OWE FUN IBAWI:
- Bi omode ba n se bi omode, agba a si maa sibi agba.
ITUNMO: Iwa ogbon lo ye ki a ba lowo agba
- Agba ku wa loja ki ori omo tuntun wo
ITUNMO: Agba je olutona iwa rere fun awon omode ni awujo
- A n gba oromodie lowo iku, o ni won o je ki oun lo ori aatan lo je
ITUNMO: a n pa owe yii fun eni to ba wa ninu ewu kan ti a si s fun-un to sin fe se ife inu ara re.
- OWE FUN IKILO:
- Aguntan to ba ba aja rin a je igbe
ITUNMO: Ti awon agba ba se akiyesi pe enikan n ba eniyan buburu kan rin, won yoo fi owe kilo fun pe ki o yera ki o ma ba a ti ibe ko iwa buburu.
- Alaso ala kii ba elepo sore
ITUNMO: Oniwa rere kii ba eniyan buruku rin
- Ise ni oogun ise
ITUNMO: Eni ba fe segun osi a tepa (mura) mo se
- OWE FUN IMORAN
- Agba to ba je ajeeweyin ni yoo ru igba re de ile koko
ITUNMO: Agba to ba hawo ko ni ri omode jise fun oun
- Igi ganganran ma gun ni loju ati okere ni a ti n yee
ITUNMO: Ohun ti o le se akoba fun eniyan ko gbodo ja fara lori re
- Bi ara ile eni ba n je kokoro arinya, bi a ko ba so fun un, here-huru re ko ni je ki a sun loru
ITUNMO: Bi ara ile eni ba n huwa ibaje ti a ko ba so fun un, nigba ti wahala tabi ijiya re ba de yio ta ba ni
- OWE FUN ALAYE
- A ni ka je ekuru ko tan ni abo, n se ni a tun n gbon owo re sinu awo tan- n- ganran
ITUNMO: awon agba maa n pa owe yii bi wahala tabi ede aiyede kan ba sele ti won si n gbiyanju lati yanju re, ti won tun wa se akiyesi pe awon kan fe hu u sita ( awon kan ko fe ki o tan )
- Agba to n sare ninu oja ni, bi nnkan o le, a je pe o n le nnkan
ITUNMO: Eni to n sise karakara mo idi ti oun fi n se loju mejeeji
- OWE FUN ISIRI
- Bi ori ba pe nile yoo dire
ITUNMO: Bi iya ba n je eniyan de ibi lo pe o fe bohun, won a maa pa owe yii lati fun un ni isiri pe ojo ola yoo dara
- Pipe ni yoo pe, akololo yoo pe baba
ITUNMO: Ko si ipenija ti eniyan le maa la koja, o le dabi eni pe ko sona abayo sugbon ni ikeyin ireti wa.
IWULO OWE
- Owe maa n je ki a fi ododo oro gun eniyan lara lai ni binu
- Awon agba n lo owe lati so oro to ba wuwo lati so
- Owe n gbe ogo ede yo
- A n lo owe lati fi ba ni wi fun iwa ti ko dara
- A n lo owe lati kilo iwa ibaje
- A n lo owe lati fi gbani ni yaju
Awon agba n lo owe lati fi yaju oro to ta koko
See also
AKORI EKO: ITESIWAJU AWON ORISA ILE YORUBA