Eya ara ifo ni awon eya ara ti a fi maa n pe iro jade ni enu. Apeere ni: iho imu, kaa enu, aja enu, tan-an-na, gogongo, komookun, edo fooro, ete oke, ete isale, eyin oke, eyin isale, erigi oke erigi isale, eyin ahon, iwaju ahon, eyin ahon.
EYA ARA IFO
- EYA ARA IFO TI A LE FOJU RI: awon eya ara wonyi ni a le fi oju ri. Apeere: iho imu, kaa imu, aja enu, tan-an-na, gogongo, komookun, edo-fooro, ete oke, ete isale, eyin oke, eyin isale, erigi oke, erigi isale iwaju ahon, aarin ahon ati eyin ahon, afase, olele, aja enu, ita gogongo, kaa imu.
- EYA ARA IFO TI A KO LE FI OJU RI: eya ara ifo ti won wa lati inu ikun si inu ofun ti a ko le fi oju ri. Awon ni: kaa ofun, inu gogongo, tan-an-na, komookun, eka komookun, edo-foro, eran edo-fooro, efonha.
AFIPE
Afipe ni awon eya ara-ifo ti won wa ni opona ajemohun. Awon ni won n kopa ninu pipe-iro ede jade. Opona ajemohun bere lati oke alafo tan-an-na de iho enu ati imu. Afipe pin si meji: (i) Afipe Asunsi ati (ii) Afipe Akanmole.
- Afipe Asunsi: awon afipe wonyi ni won maa n sun nigba ti a ba n pe iro. Apeere: ete isale, eyin isale, erigi isale, ahon, gogongo, olele.
- Afipe Akanmole: awon afipe yii ki i sun lo si ibi kan ti a ba n pe iro. Apeere: eyin oke, ete oke, erigi oke, aja enu, kaa imu afase.
IGBELEWON
- Ko afipe asunsi marun-un sile.
- Ko afipe akanmole marun-un sile.
- Ko eya ara-ifo marun-un afojuri marun-un sile.
- Ko eya ara-ifo marun-un sile.
IWE ITOKASI:
Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd. o.i 5-8.
EGUNGUN
Egungun je okan pataki lara esin ibile Yoruba. Orisa egungun je orisa ti awon Yoruba fi maa n se iranti awon baba nla won. Ologbojo ni olori egungun. Eku ni won maa n dab o ori won. Igbale ni won maa n gbe eku egunngun pamo si. Irisi won jo tie sin gelede. Orisiirisii aso ni o maa n wa lara eku egungun. Awon elesin egungun ni won maa n je ‘oje’ Ojewale. Ojetunde, Ojegbenro ….
IGBAGBO YORUBA NIPA EGUNGUN
- Yoruba gbagbo wi pee sin egunfun je esin aseynwwaye
- Yoruba gbagbo wi pe o je esin lati orun.
- Awon yoruba gbagbo wi pe egungun je baba nla awon.
IGBELEWON
Salaye lori esin egungun.
IWE ITOKASI:
Adewoyin S.Y (2014) IMO, EDE, ASA ATI LITIRESO YORUBA fun ile eko girama agba S.S.1 Corpromutt Publisher Nig Ltd.
APAPO IGBELEWON
- Salaye lori esin egungun.
- Ko afipe asunsi marun-un sile.
- Ko afipe akanmole marun-un sile.
- Ko eya ara-ifo marun-un afojuri marun-un sile.
- Ko eya ara-ifo marun-un sile.
ISE ASETILEWA
- Eya ara-ifo ti a le fi oju ri ni (A) oju (B) ori (C) ete (D) edo foro
- Eya ara-ifo ti a ko le fi oju ri ni (A) edoforo (B) ete (C) eyin (D) eti.
- Ewo ninu awon wonyi ni o maa n sun ti ba n pe iro? (A) agbon (B) ete isale (C) ete oke (D) eyin oke.
- Ki ni aso egungun? (A) sapara (B) kenbe (C) eku (D) adiro
- Esin wo ni o fi igbagbo Yoruba han nipa iye leyin iku? (A) kokumo (B) oro (C) Obatala (D) egungun.
APA KEJI
- Se iyato laarin afipe akanmole ati asunsi pelu apeere.
- Ki ni igbagbo Yoruba nipa esin egungun?
See also