ITAN NIPA ORUNMILA
Okan pataki ni Orunmila je ninu awon okanlenirinwo Irunmole ti won ti ikole orun ro si Ofe Oodaye. Ni Oke Igbeti ni Orunmila koko de si ki o to lo si Oke Itase. Idi niyi ti won fi n ki i ni ‘Okunrin kukuru Oke Igbeti’.
Orunmila ni alakoso Ifa dida ati tite ile. Owo re ni akoso aye nipa ogbon ati imo ohun ti yoo sele lojo iwaju wa. Ko si oro kan ni abe orun tabi oro kan nipa isenbaye, ogbon ati igbagbo awon Yoruba ti Ifa ko so nipa re.
Gege bi Ojogbon ‘Wande Abimbola ti so ninu iwe “Awon Oju Odu Mereerindinlogun”, Orunmila lo opolopo odun ni Ife Oodaye, ki o to lo si Ado, ibi ti o ti pe ju lo ni ode aye. Idi niyi ti won fi n so pe ‘Ado n’ile Ifa’. Orunmila tun gbe ni Otu Ife.ibe ni o ti bi awon omo wonyi: Alara, Ajero, Owarangun-aga, Oloyemoyin, Ontagi-olele, Elejelu-mope ati Olowo. O tun gbe ni Ode Oyan, ibi to ti bi Amukanlode-Oyan. Bakan naa ni o gbe ni ode Onko, to ti bi Amosunlonkoegi.
Out-Ife ni itan so pe Orunmila ti pada si ode orun, ti ko si was i aye mo nitori iwa arifin ti Olowo, abikeyin omo re ni Otun Ife hu si i ni ojo ti Orunmila se odun. Orunmila ranse si awon omo re pe ki won w aba oun se odun. Bi won ti n de ni won n fori kanle ni okookan, ti won n so wi pe ‘aboruboye bo sise’. Igba ti Olowo de, o duro, o ni oun ko le wi ‘aboruboye bo sise’. Orunmila beere idi to fi se bee, Olowo ni:
“Iwo Orunmila sodun, o sodun ko;
Oun Olowo naa sodun, oun sodun ko
Iwo Orunmila f’osun ide lowo;
Oun Olowo naa f’osun ide lowo
Iwo bo salubata ide
Oun Olowo bo salubata ide…..
Iwo Orunmila dade
Oun Olowo naa dade,
Bee ni won sin i
Enikan ki i fori ade bale fenikan…..”
Oro yii lo mu Orunmila binu gba Osun Ide owo Olowo, o kori si idi Ope Agunka, ibe ni o gba lo si orun. Nigba ti Orunmila lo tan ni gbogbo nnkan daru, aye ko roju mo. Gbogbo aye lo be awon omo Orunmila ki won ba won be baba won. Igba ti won de idi ope agunka ti Orunmila do si, won be e titi, Orunmila da won lohun pe oun ko tun pada wale aye mo. O wa fun won ni ikin merindinlogun, ti o fi ropo ara re. O ni:
B’e e ba dele
B’e e f’owoo ni
Eni t’e e moo bi nu-un….
Lati igba naa ni ikin ti di ohun elo pataki ti awon babalawo fi n beere nnkan lowo Orunmila.
IGBAGBO YORUBA NIPA ORUNMILA
- Orunmila alakoso Ogbon, Imo ati Oye
- Opitan ni Orunmila
- Okunrin Kukuru Dudu ni Orunmila
- Orunmila ni alakoso Ifa dida ati tite ale
- Orunmila ko ni egungun lara lati sise agbara
- Agbaye-gborun ni Orunmila
BI WON SE N BO ORUNMILA
Ojo awo ni won bo Orunmila, bi o tile je wi pe ojoojumo ni awon babalawo n bo Ifa. Bi won se n difa oroorun naa ni won n se odun Ifa ni odoodun.
Ti won ba fe bo Ifa ni owuro, babalawo yoo mu obi si inu omi tutu, yoo maa fi iroke lu opon Ifa, yoo maa ki Orunmila ni mesan-an-mewa. Babalawo yoo pa obi naa, yoo se oju yii si inu omi. Omi naa ni yoo lo da fun Esu. Babalawo yoo wa da obi naa mo bi Ifa ba gba a. bi obi bay an tako tabo, iyen ti meji si oju, ti meji da oju de ile, Ifa ti gba obi nu un. Babalawo yoo pin obi fun awon to wa nibe lati je.
Bi o ba je Ifa odun, awon nnkan repete ni won yoo ka sile. Won yoo sip e mutumuwa fun ariya.
OHUN TI WON FIN N BO IFA
Eku meji, Eja meji, Igbin, Ewure, Adiye, Isu, Aguntan, Osuka omu ati obi.
AWON OHUN ELO IFA
Opele, Apo Ifa, Iroke Ifa, Opon Ifa.
Opon-Ifa ti a fin ona si lara, Iyerosun, Iroke, Ibo, Opele, Ikin merindinlogun, Awo-Ifa, Opa Osooro, Irukere.
SANGO: ITAN SANGO
Eniyan ni a gbo pe Sango je ki o to di orisa. Sango je orisa ti ise, irisi ati isoro re kun fun iberu. Sango je omo Oranmiyan. Awon iyawo re ni Oya, Osun ati Oba.
Itan so nipa Sango pe o je Oba l’ode Oyo-ile. Gege bi Oba alagbara, onigboya to tun loogun, o feran lati maa fi agbara re han awon eniyan. Bi Sango ba n soro ina a maa jade ni enu re. Ijoye tabi ara ilu to ba ni ti Sango bawo yoo je iyan re ni isu. A gbo pe Sango lo da ija sile laarin ijoye ilu meji, ti okan fi pa ekeji ku fininfinin.
Bayii ni Sango n da ilu ru, ti tomode-tagba ilu fi dite mo on. Igba ti ote yii kojaa siso, Sango ko eru re, o sa kuro l’ode Oyo. Awon iranse re, Osumare ati Oru pada leyin re. sugbon awon iyawi re meteeta n tele leyin lai mo ibi kan pato ti won n lo. Igba ti Sango rin die si Oyo, to ri pe oun ko leni lehin mo, afi Oya, ironu mu un, o way a si idi Igi Ayan, o si so ara re mo ibe, ti a n n pe ni Koso. Oya, iyawo re sa lo si apa ariwa, wole ni Ira, o si di odo Oya. Awon ero ti n koja ri Sango, won n yo suti ete si i pe ‘Oba so!, Oba so!’. Oro yii ko dun moa won eniyan Sango ninu, won si yo kelekele lo si ilu Ibariba lati gba oogun buburu ti won fi n baa won ota Sango ja. Igba miiran, won a yo kelekele fi in abo ile ni orun, won a ni Sango lo n binu. Ti ojo ba ro ti ara san, ti ‘edun ara’, ti o je okuta ba pa eniyan, won a ni Sango lo n binu. Idi niyi ti a se n pe Sango ni ‘Jakuta’. Igba ti wahala yii po ni awon ara Oyo bay i ohun pada, won n so pe ‘Sango Oba Koso’, ki won ma baa ri ibinu re. iberu yii ni won fi so Sango di orisa titi di oni.
Ilu Oyo ni odun Sango ti gbayi julo ni ile Yoruba. Won tun n se odun re ni Ibadan, Iseyin, Iwo, ede, Abeokuta, Ilesa, Ondo ati Ekiti. Awon aworo re ni a n pe ni Onisango tabi Adosun-Sango. Awon asaaju won ni a n pe ni Magba tabi Iya Magba. Adosun-Sango maa n di irun ori, won n wo aso osun ti Sango feran ju lo nigba aye re. Awon aworo re maa n mu Ose Sango lowo. Ilu bata ni ilu Sango Ounje ti Sango feran ni amala pelu obe eweedu, eran agba, orogbo ati obi. Idi niyi ti won fi n ki i ni: Sango oloju Orogbo, eleeke Obi.
IGBAGBO YORUBA NIPA SANGO
- Orisa to ni agbara lori ara ati imonamona
- Orisa afajo
- O n fun won lomo
AWON OHUN ELO SANGO: Bata, ilu Sango, Ose Sango, Sere Sango, Laba Sango
OHUN TI WON FI N BO SANGO: Orogbo ni obi Sango. Won n fi oka, adiye ati aguntan bolojo bo. Ounje Sango ni oka.
ORIKI
Penpe bi asa, asode bi Ologbo
Sangiri-lagiri!
Olagiri kaka f’igba edun bo o!
Eefin ina l’a nda l’aiye
Ina mbe l’odo oko-mi orun
Sango Onibon orun
Ajalaji Oba Koso
Ewelere okoo mi
Aara-sowo-ija-lala!
Aara-o-fija-wole!…..
See also
AKORI EKO: ITESIWAJU ONKA YORUBA
AKORI EKO: ITESIWAJU EKO LORI ONA IBANISORO
AKORI EKO: AROKO ONI-SORO-N-GBESI