Gbolohun ni oro tabi akojopo oro ti o ni itumo. Gbolohun le je ipede ti o ni itumo tabi ni ise ti o n se nibikibi ti o ba ti jeyo. Bakan naa a le pe gbolohun ni oro ti a le pin si spola oro-oruko ati apola ise.
ISORI GBOLOHUN EDE YORUBA
- Gbolohun eleyo oro-ise tabi gbolohun abode
- Gbolohun alakanpo
- Gbolohun ibeere
- Gbolohun olopo oro-ise
- Gbolohun alaye
- Gbolohun ase
- Gbolohun iyisodi
- Gbolohun iba tabi kani
- Gbolohun akiyesi alatenumo
- Gbolohun asodoruko
- Gbolohun eleyo oro-ise tabi gbolohun abode: eyi ni ipede tabi afo ti o ni oro-ise kan ninu. Irufe gbolohun yii ni a tun mo si gbolohun kukuru. Bi apeere:
- Bisi sun
- Dayo gun igi
iii. Fadekemi we gele
- Gbolohun alakanpo: eui ni ipede tabi gbolohun ti a lo oro asopo lati so gbolohun meji tabi ju bee lo po di eyo gbolohun kan soso. Bi apeere:
Ile re tobi, iyara re kere = ile re tobi sugbon iyara re kere
Temidayo lo si ibi ayeye naa
Adeyemi lo si ibi ayeye naa
= Temidayo ati Adeyemi lo si ibi ayeye naa
- Gbolohun ibeere: eyi ni awon gbolohun ti a fi n se ibeere. Awon wunren gbolohun ibeere ni, da, nko, tani, ati bee bee lo. Bi apeere:
Adegoke da?
Badejo nko?
Ta ni o wa nibe?
- Gbolohun olopo oro-ise: gbolohun yii naa ni a mo si gbolohun onibo. Gbolohun yii maa n ju eyo oro-ise kan lo, oro-ise inu gbolohun yii le je meji tabi meta. Bi apeere:
Mo jeun mo si yo
Won n rin won n yan won si se oge
Ise asetilewa: Ko apeere meji lori orisii gbolhun ti o mo
ITESIWAJU ISE LORI ISORI GBOLOHUN
- Gbolohun alaye: eyi ni gbolhun ti a n lo lati so bi n kan se ri. Bi apeere:
Won ti jewo bi oro ti se ri gan-an
Iwe meweaa ni Bolude ka
Ojo naa fere wu oku ole
- Gbolohun iba tabi kani: eyi ni gbolohun ti a fi n so bi nkan se ri ati idi ti o fi ri bee. Atoka re ni ‘bi’, ‘kaka’, ati ‘dipo’. Bi apeere:
Bi mo ma lowo maa dara
Kaka ki n jale, maa di eru
Dipo ki n ra eran, maar a eba
- Gbolohun iyisodi: awon oro atoka gbolohun yii ni ‘ko’, ‘kii’, ‘ko’, ‘ma’. Bi apeere:
Bisi ko wan i ana
Femi o ri osere naa
Akande kii wa si ipade dede
Jegede kii je ewa
- Gbolohun akiyesi alatenumo: A maa n fi pe akiyesi si apa ibikan pato tabi koko kan ninu odidi gbolohun nipa lilo ‘ni’ ninu gbolohun abode ti a fe se atenumo. Bi apeere:
Mo ra ile tuntun ni Abuja
Rira ni mo ra ile
Abuja ni mot i ra ile tuntun
- Gbolohun Ase: Eyi maa n waye nipo ipede ti o je kan-an nipa fun eniti a ba soro. A maa n lo o gege bi igba ti a fi n mu u je dandan fun eni naa. Bi apeere:
Dake je!
Dide duro ati bee bee lo
Ise asetilewa
Ko apeere kan-kan lori orisii gbolohun ti o se le ni ki o si ko meji lori gbolohun asodoruko.
See also
AKORI EKO: APOLA INU EDE YORUBA