Aroko ti a ko to da lori itakuroso laaarin eniyan meji tabi ju bee lo ni a n pen i aroko oni-soro-n-gbesi.
Abuda Aroko Onisoro-n-gbesi
- O maa n ni akopa bii ere ori itage
- Oro enu akopa kookan maa n han ni iwaju oruko won
- Iso bee ko gbodo gun ju, ko si se regi
- Oro erin ati awada kii gbeyin, a si gbodo year fun awada ako
- Isesi won ni a maa n fi sinu ami akamo olofo ( ).
E je ki a ka aroko oni-soro-n-gbesi yii wo, bi apeere:
(Won sese gbe oga titun kan de si ile-iwe re, ko iforo-jomi-tooro oro to waye laarin akekoo meji lori oga titun yii sile).
OGA TITUN
(Ranti ati Yemisi wa ni Kilaasi S.S.2. Won pade ni ikorita meta ni eba ile ounje. Yemisi fe lo kawe, Ranti fe lo pon omi)
Ranti: (o sunmo Yemisi) E ma si ku amojuba t’Oga titun
Yemisi: Baa se ki ni naa nu un. N o kuku tii ri won soju
Ranti: Ma je k’aye o gbo. Iya to wa si ipade apejopo akekooati oluko ni aaro ana
Yemisi: (o mo’ju tai) Se won ni mow a n’be ni? Mo pe de. Kilaasi ni mo gba lo taara
Ranti: Eyin isa-n-sa. Oju yin re e. ipade ohun ma larinrin
Yemisi: Ki lo sele? Won fun yin lo’oyin la? Gbee si mi leti, joo
Ranti: Oyin ko, ado ni. Won kan fi oga han wa ni. Oun alara si gba wan i iyanju pe ki a tepa mose.
Yemisi: Eyuun lo wa mu ipade dun? Osise ni wan i?
Ranti: Ki lo fe ki iya-oniyaa so? Oro iyanju ni akekoo n fe. Abi lo fe ko so. O kuku ti se’pade pelu awon oluko ati awon pirifeeti.
Yemisi: (O tewo pe e) Igba wow a ni ‘pade tiwa? Abi?
Ranti: Ipade wo ni o fe ki Alaaja tun ba wa se?
Yemisi: Wa na, se Musulumi ni?
Ranti: Musulumi ponbele ma ni. O kirun ju awo lo. Oro po. Iya naa le soro lataaro dale!
Yemisi: Awon akekoo Musulumi bo saye nu un. Logan ni yoo ko Mosalasi ti won ti ko pati lati bi odun merin.
Ranti: O ma ni oun ko boroesin wa. O ni bi esi idanwo asejade wa yoo se gbe peeli soke sii ni o je oun logun.
Yemisi: Too. Olorun a fun un se. Awon alale a tii leyin
Ranti: Ti awon alale ti se wa je ninu oro ile iwe?
Yemisi: Ki lo fe n so? Se bi, won ni ‘Isese lagba’?
Ranti: Ooto ma kuku ni. Obatala a ba a f’ase sii
Yemisi: Ase o
(won pinya)
ALAYE
Iwontunwonsi afo enikookan se regi. Ede won lo taara, bee ni awada ibe mo niwon. Akekoo
meji pere ni a lo. Ko dara ki akopa po repete.
ISE AMUTILEWA
- Ko abuda aroko oni-soro-n-gbesi marun-un ti o mo
- Ro o lokan ara re pe iwo (Femi) ati ore re (Bayo) lo woran are Boolu afesegba to waye laarin Super Eagles ati iko agbaboolu Argentina. Super Eagles feyin won bale ni amin ayo merin si ookan. Eyin mejeeji wa n foro jomi-tooro or obo wa si ile. Bi oro naa se lo re e:
See also
AKORI EKO: ATUNYEWO ISE ABINIBI
AKORI EKO: ATUNYEWO LORI SILEBU EDE YORUBA
AKORI EKO: AROKO AJEMO – ISIPAYA
AKORI EKO: ATUNYEWO AAYAN OGBUFO