Aroko ajomo-sispaya je aroko ti a fi n se isipaya awon ori oro to je mo ohun ayika eni. Aroko yii fi ara jo aroko asapejuwe sugbon o jinle ju u lo. Bi aroko asapejuwe se le fe ki o sapajuwe ‘Ile-iwe re’, aroko ajemo isipaya yoo fe ki a so nipa idagbasoke to de ba gbogbo nnkan ile iwe naa titi de ori eto isakoso. Aroko ajemo isipaya maa n tu isu de idi ikoko ijinle itumo, anfaani ati aleebu ori oro.
Eyi tumo sip e aoko ajemo isipaya pe fun imo to gbooro nipa sisafihan bi nnkan won se ri tabi sise. Ki akekoo to le yege ninu aroko ajemo isipaya, o gbodo nifee si ise iwadii nipa nnkan ayika, ki o si ma aka orisirisii iwe, jona ati iwe-iroyin, ti yoo fun un ni imo kikun nipa nnkan ayika.
Aroko ajemo isipaya le je eleyo-oro tabi apola ti won ni itumo to jinle. Apeere aroko ajemo isipaya ni:
- Omi
- Iwe iroyin
- Ise Tisa
- Oge-Sise
- Imototo
- Aso ebi
Aroko ajomo-isipaya tun le je ori-oro bii:
- So awon nnkan ti iwo o se ti won bay an o ni alamojuto eto iwosan ni agbegbe re
- Se ekunrere alaye bi iwo yoo se seto ayeye odun ibile laarin awon akekoo ile-iwe re.
E je ki a ka aroko ajemo isipaya yii wo, bi apeere:
OWO EYIN
Orisirisi iwa ibaje lo maa n fa Orile-Ede seyin. Okan ninu iru awon iwa ibaje bee ni gbigba ati fifuuni ni owo eyin. Iwa yiiti gbile ni Orile-Ede wa. Bi o tile je pe opo awon eniyan nla lo wa ni idi iwa yii, sibe eyi ko so di nnkan to dara. Ani ohun ti ko dara ko ni oruko meji, ko dara ni. Orisirisi oruko ni awon eniyan fun owo-eyin. Awon kan n pe e ni ‘Owo-abetele’. Awon kan n pe e ni ‘sowo kuduru’. Awon miiran si n pe e ni ‘riba’. ‘Owo ibole’ ni awon kan mo on si. Oun kan naa ni won n pen i ‘owo pabe’ tabi ‘owo ijule’. A ri awon ti n pe e ni ‘egbo’. Ko si oruko ti a pe ata ti a le mu tita ata kuro. Ani ko si oriki ti a le fun iwa-ibaje yii ti o le so di nnkan rere.
Ki i se owo nikan ni awon eniyan n lo gege bi abetele. Awon miiran n ra nnkan gege bi ebun, won o si fi se riba. Bee ni a si ri awon obinrin ti won n fi ara won dipo owo abetele. Ohun ti o daju ni pe ni gbogbo kolofin awujo wa ni iwa yii ti gbile bi owara ojo. Ko si si eni ti o le gba riba ti yoo se eto. Bi adajo ba gba a, too gbe ejo are fun elebi.
Olopaa ti o gba a ko ni le mu odaran. Wolewole to ba gba a yoo maa gba iwa idoti laaye laarin awon eniyan. Oluko to gba a ko ni salaida esi idanwo ru.
Asa awon kan ni pe ko si ibi ti won ki i ti fun ni lebun. Won ni ko si ibi ti iwa yii ko si, won lo tile wan i ilu awon oyinbo Geesi. Iro patapata gbaa ni eyi. Bi o ba tile wa nibe, eyi ko so di iwa daradara. Ohun ti won n se ni ohun ni fifi emi imoore han. Bi a ba se enikan lore, yoo si fun wa ni nnkan ami ope re. Ki i se pe owo la o beere fun nnkan naa. Bee ni ko pon dandan ki o fun wa. Awa naa maa n se iru eyi ti o wopo loke-okun ni Orile-Ede yii. Gege bi apeere, bi enikan ba ran wa ni eru, a oo wa nnkan fun un. Bee si ni a maa n fi imoore han fun eni toju wa ni ile ounje.
Ko si ona ti a gba wo owo ibole ti o so di nnkan rere. O ye ki gbogbo eniyan yera fun iwa abetele ki Orile-Ede wa le niilosiwaju. Bi a ba yera fun iwa abetele, onikaluku yoo le gba eto re. A o si fi ogun asa rere titun sile fun awon omo ti yoo ropo wa ni eyin-ola.
ALAYE: Aroko yii ko gun, sugbon o je apeere ajemo isipaya. Bii abuda, ori-oro yii jinle. O gba ki akeeko ni imo kikun nipa owo eyin. E je ki a woe to aroko yii:
ETO
- Ifaara: o sipaya orisii itumo ti ‘Owo eyin’ ni ipin-afo kin-in-ni ati ikeji. Oun yii dara pupo.
- Koko-Oro: Gbolohun ipari ipin afo keji ati iketa ni ni alaroko ti n so ewu owo eyin bi o se le dena eto eni si idajo ododo.
- Ikadii: Ikadii aroko yii fi han pe yiyera fun iwa yii lo le mu ilosiwaju ati eto idajo ododo wa ni awujo
E je ki a tun wo apeere aroko ajemo isipaya yii wo.
OWO
Koseemanii ni owo je fun eda. Owo ni ohun ti a n na tabi fi ra nnkan. Ire meta ni eda n wa ni ile aye, bi Ifa, elerii-ipin se la a sile. O ni “Ninu gbogbo ire ile aye pata poo, meta l’o se pataki ju. Awon ire meta naa ni ire owo, ire omo, ire aiku (tabi alaafia) pari iwa.” O ni:
Ire meta l’awa n wa
Awa n wowo o,
Awa n womo,
Awa n wa atunbotan aye.
Ifa ni ‘Eni ti o ba ti ni awon ire meteeta wonyi ti ni iyoku. Eni ti o ba lowo yoo niyawo, yoo kole, yoo si ni aso. Idi niyi ti owo fi je egbon fun gbogbo ire yooku.’
Owo yii ni awon Yoruba pen i ‘aje, Ogungun-niso’. ‘Owo, apekanuko’. Awon Hausa pe e ni ‘Kudi, eya ibo pe e ni ‘Ego’.
Ni orile ede Naijiria, owo Naira ati Kobo ni a n na. Awon ilu okeere bi ilu Oba n na owo Dola, orile ede Amerika n na ‘Poun’, bee ni awon orile de agbaye miiran si n na ‘Euro’. Owo ibaa je dola, poun tabi naira, ‘nina lowo’. Ojuse pataki kan ti a mo on mo niyi. Won eni to ba n nawo ni a n pe ni ‘nawo-nawo’, alowo-lowo maa lee owo da. O le kole alaruru, o le ra obokun-oloye, o le fe iyawo. Owo ni a fi n se ohun gbogbo. Awon ayan a maa lulu pe “Olowo sehun gbogbo tan, iya ni o je omo talika”. Gbajumo olorin kan tile tusu de idi ape ninu orin re yii:
“Ohun gbogbo t’Oluwa o se fun wa,
Ma j’owo o gbehin rara
Tori oro t’owo ba se ti
Ile lo n gbe
E wa wohun t’owo se o
Nile aye ta wa yii
Owo ni n se nnkan ‘re
Owo ni n se nnkan gidi
Edumare fun mi ni ‘Moni’ o
Ki n r’owo fi jaye.”
Bi owo se se pataki to, tolori telemu ni n wa a kiri. Kaakiri agbaye ni awon eniyan ti n sare owo. Won ni “Ohun ta o sonu ti gbogbo wa n wa kiri”. Ona kan gboogi to mo ti a fi le ri owo ni ki a tepa mose nitori ‘Oju boro ko ni a fi n gbomo lowo ekuro’.
Orisiirisii owo lo wa. Owo tutu ati owo gbigbona. Owo ti a fi oogun oju eni ko jo ni a mo si owo tutu. Owoo-gbona ni owo won fi ona eru ko jo. Ohun ni won tun n pen i owo eje, owo okuta ati bee bee lo.
Okan-o-jokan ipede awon Yoruba fi pataki owo han. Won ni: ‘Owo ko si, eniyan ko suwon’, ‘owo ni ti oun ko ba si nile ki enikeni ma dabaa Kankan leyin oun.’ ‘Owo ni so omode di agba, oun naa ni so agba di ewe.
Owo a maa fun eniyan ni iyi. Ojuse owo kan niyi. Awon Yoruba a maa fi owo ra iyi. Won ni ‘A n wa owo lo, a pade iyi lona, ti a ba ri owo oun tan, iyi naa ni a o fi ra.
Owo ni a fi n pinle owo, ola ati ola. Opomulero ni owo je fun owo. Won ni “Owo la fi i peena owo, bi egbaa ba so soke egbaa la a fi ja a sile.’ Ipede wonyi fi han pe owo se koko ninu owo-sise. Won tile ni ‘Olowo lo lowo.’ Sugbon igbagbo w ape eni ti o ba n se eru nidii okowo, owo bee ko ni mo on lowo. Won ni ‘eni to ba taja erupe yoo gbowo okuta’. Owo okuta tumo si owo ti ki i duro lowo.
Oye owo ti a bar a oja n so bi a o se karamaasiki nnkan naa si. Bi a ko ba fi owo ra nnkan, a ki i mo iyi iru nnkan bee. Eredi ti won fi ni ‘Oogun ta a ba fowo se. eyin aaro ni i gbe.’ ‘Bia bas i fi owo ra ooyi, dandan ni ki o ko ni loju’. Oro agba niyi.
Bi owo se niyi to yii, awon Yoruba ni ‘Owo ni gbongbo ese.’ Gbongbo ni emi igi. Ti a ba si wa ni ‘owo ni gbongbo ese, eyi tumo si wi pe owo n fa ihuwasi ti o lodi si ilana ofin yala ti ofin Olorun, ti ijoba tabi ti awujo. Orisiirisii ona ni eda fi wa owo. Won n lu omolakeji ni jibiti, ti a mo si ‘gbajue’, bee ni won fi eniyan soogun owo! Ese si ni gbogbo iwonyi lodo Olorun. Bee ni “Elese kan ko ni lo laijiya” ni iwo Mimo so.
Ailowo lowo, won pe e ni ‘baba ijaya’. Okorin kan tile ko lorin, bee naa ni o tun so wipe owo tun n sokunfa igberaga, bee ni ‘igberaga ni saaju iparun’. O ko o pe:
“Oro gbogbo lori owo
Yesi, otito ni
Aini owo baba ijaya
Yesi, otito ni
Alowo lowo, baba afojudi
Yesi, otito ni……..
Koseemani ni owo je. Ko si ohun tie da le se lai si ‘Kudi’?
Kirakita eda nitori aje ni. Owo, ohun ta a sonu, taa n wa kiri! Owo, apekanuko.
ALAYE: Aroko yii gun. Bi aoko ajemo-sispaya, a ri oniruuru oruko ti a n pe owo, oriki, iwulo, anfaani ati alebu re. tun aroko yii ka, ki o sit un n ko niwonba.
AMUTILEWA
- Ko igbese leta aigbagbefe mefa ti o mo sile leseese.
- Ko aroko ajemo isipaya lori awon ori oro wonyi:
(i) Iku (ii) Iyan (iii) Ohunosin
AKORI EKO: ATUNYEWO EKO – ILE
Ni ile Yoruba, awon eko ti awon obi maa n ko omo lati kekere ni a n pe ni eko – ile. Yoruba ni “Ile ni a ti n ko eso rode.” Awon eko bee ni ikini, imototo, isora, iwa to to si obi, agbalagba, alejo, ati elegbe-eni. Omo ti won ko, to si gba, to si n mu eko naa lo nigba gbogbo ni a n pe ni omoluabi. “Omo-Olu-iwa-bi”. Olu-iwa ni eni ti o je orisun gbogbo iwa rere aye. Bi enikeni ba si je omo re, oluwa re ko ni sai ni ekun iwa rere; eni ti o ko gbogbo iwa rere po, ti gbogbo elegbe ati olugba ka si ojulowo eniyan. Owe Yoruba ni “iwa rere ni eso eniyan”.
Abuda omoluabi po jantirere. Ara re ni owo, iteriba fun agba, osise, oninuure, onisuuru, eni ti ko je huwa abosi tabi ireje si enikeji. Awon ona ti omode le gba huwa omoluabi niwonyi:
(i) Ibowo fun Agba: Awon obi a maa ko awon omo bi won se gbodo maa bowo fun agba. Won ni “Omode to bam o owo we yoo ba agba jeun”. Eyi ni pe, omode to ba ni iwa pele ati iwa rere yoo ma aba awon agba rin. Oniruuru iwa rere ni omode le hu si agba.
Ekini ninu won ni ibowo fun agba. Owe Yoruba ni “Aibowo fun agba ni ki i je ki aye gun.” Omode ki i yaju si agba. Omokomo ti o ba daa an wo, iya ni iru won n je.
Ona keji ni pe, bi agbalagba ba n soro, omode ko gbodo pariwo tabi se ayonuso si oro ti agba ba n so. Ni ile Yoruba, omode to gbeko ki i da si oro ti won ko pe e si. Bee ni omode ki i da nnkan se laisi ase agbalagba nibe. Won a maa ko ni orin:
B’agbalagba ba n soro,
K’omode kekere a woye;
Kekere ko l’Erin fi ju Ekun lo
Oro gbogbo l’owe.”
Bakan naa, bi agba ba n sise ile, omode ko gbodo maa wo o niran. Ti omode ni lati bo si ibe ki o pin ninu ise naa se ni ona ti yoo fi fuye fun agba. Bakan naa, bi agba ba ru eru nibi ti omode wa, tabi n ru eru bo lati okeere, omode ni lati gba a lori re.
EKO ILE
Ni apeje, bi agbalagba ba pe leyin, ti ijokoo ko si fun un, eto omode ti o ba wa nibe ni lati dide fun un lati jokoo si aare re. Bi o ba si je wi pe won jo de si asiko kan naa, agba ni lati ko jokoo saaju omode. Ni oju agbo tabi ipade yoowu, bi won ba n pin nnkan, ti agba ni a o ko yan.
Omode, ko gbodo pe agba loruko. A maa n fi oruko omo pe agba ti a ko le la oruko mo ni ori. Bi apeere, ‘Iya Wale’, tabi ‘Baba Kudi’, tabi ki a kuku pe won ni baba, iya, tabi egbon eni. A ki i lo ‘iwo’ fun agbalagba. “E” to fi owo han ni a n lo. “E kaaro”, “E kuuse o”, ati bee bee lo. Okan pataki ni ikini je ninu asa ibowo fun agba.
Omode ko gbodo maa ki agbalagba ki o nawo si i lati bo won lowo, bee ni iwa afojudi ni ki a ma aba agbalagba soro pelu pako ni enu laaro.
“Iwa rere ni eso eniyan”. Omode ti o ba huwa rere si agba yoo ri oore gba, ojo re yoo si pe ni aye. Awon omode to n bo leyin re yoo si bowo fun un, nitori “Aseele ni abo-aba.”
(ii) Kiki eniyan bi o se ye ni gbogbo igba: Kekere ni awon obi ti n ko omo ni orisirisi ikini. Bi omodekunrin ba ji laaaro, eto ni ki o ki awon obi re ninu ile towo-towo. “E kaaaro o, Momo” tabi “Ejiire Momo mi”. Omode ni lati fi ara re han bi omo ti o gbekoo nipa didobale bi o ba je okunrin tabi kikunle, bi o ba je obinrin. Omode ki i duro gbagidi ki agbalagba. Abiiko ni won n pe iru omo to ba huwa omugo bee. Aaro nikan ko ni a n ki ni. Omode gbodo mo bi a se n ki eniyan ni osan, irole, ale ati nigba gbogbo. Bi omode ba n ki agbalagba, yoo lo oro eni pupo fun eyo agba kan soso: ‘Mo n ki yin ni o!’ ‘Mo ba won nile’, ‘Eyin ni mo n ki, sa! Ati bee bee lo.
“E kuule” n la a ki araale, ‘E ku ona’. n la a ki ero ona. ‘Omo olokun, abaja-lorun, maa wo ‘le’ o!’ n la a ki omolooku, bee ni ‘iyawo a bi ako a bi abo o’ tabi ‘eyin iyawo ko ni mo eni o’, ni a n ki eni to sese se igbeyawo osingin. Gbogbo ikini wonyi ni omo Yoruba gbodo mo lati ewe. Eyi le le die fun omode, sugbon ‘Tita riro la a kola, bi o ba jina tan, oge ni i da’. Mimo eniyan an ki ni akoko to ye ati ona to to n iyi fun ni.
(iii) Ninu iwa Rere ati Suure: Gege bi itan isenbaye, bi awon Yoruba se gba ORI gbo naa ni won gba IWA gbo. Won gba pe bi eniyan yan ori rere, bi ko ban i iwa rere, aye ati orun re ko le dara.
Iwa ti a n wi yii, obinrin ni ati wi pe aya Orunmila ni. Orunmila ko iyawo re Iwa sile nitori o ni obun pupo, Iwa si ko lo si ile Olodumare. Se omo Olodumare ni Iwa nitori pe oun ni i se akobii Suuru, to je aremo Olodumare. Nitori eyi ni a fi maa n so pe “Suuru ni baba iwa”. Igba ti Orunmila ko iwa sile tan, ni aye re ko ba dara mo. Ko ri se mo, ko ri je, ko ri mu, bee ni gbogbo eeyan lo n ri i ho. Nigba ti aye Orunmila waa dorikodo nitori pe iwa nu-un, lo ba mura lati wa obinrin re lo. Nitori “Bi iwa ba nu eeyan, aye re lo nu un….” Bayii ni Orunmila se bo sinu eku Eegun, o bere si i wa Obinrin re kaakiri. O wa a de’le Alara, eji osa, omo amurin kan dogbon agogo. O wa a de’le Ajero, omo ogboju koro ija jale. O wa a de’le Owarangun aga, amota ede, oniguru, agun f’owo laba owo teteete. O wa de gbogbo ilea won oloja mereerindinlogun, sugbon ko ri i. L’o bag bona orun lo. Nibe l’o ti war i Iwa. O bere si i be e pe ki o ba oun kalo si ile, sugbon Iwa ni oun ko lo. O wa ki Orunmila ni ilo pe ki o maa fi owo re tun iwa ara re se laye. Lati ojo naa l’o ti di wi pe owo onikuluku l’o fi tun iwa ara re se. eyi ko ni wi pe iwa ati suuru se pataki. Ara abuda eko ile ni.
Yoruba n ko omo pe bi a se n toju obinrin eni ni a se n toju iwa eni. Bi eeyan ba w alai ni iwa, egbe ati otubante ni. Won ni:
B’a a lowo
B’aa niwa
Owo olowo ni
Iwa, iwa l’a n wa o,
Iwa……
Ara awon iwa rere ti omo n ko ni ki a ma so otito, ki a si maa ni suuru. O ni:
Ibinu ko da nnkan kan fun ni
Suuru baba iwa
Agba t’o ni suuru
Ohun gbogbo l’o ko ja….”
Omode ki i wo agba loju, bee ni won ko gbodo su agba lohun bi won ba n ba won wi. Igbesi aye re gbodo maa je apeere suuru ati irele okan, ti yoo je awokose fun awon eniyan.
(iv) Ninu Iforiti: Iforiti se koko ni aye eda. Bi isoro ba de, a gbodo ko omode bi won se n fi ori ti i, ti won ko fi ni bohun tabi kaaare. Yoruba ni “Iforitu lo ni ohun gbogbo”. Iforiti ni a fi n segun isoro yoowu ti i baa doju ko ni. Pelu iforiti, omo yoo le se ohun ti won ro wi pe o koja ogbon ori re.
(v) Otito ati Oro Rere Siso: Otito siso je okan gboogi ninu ohun ti obi n ko omo lati kekere. Won ni ki a soro ki a baa bee ni iyi omo eniyan. Lati pinnisin ni a ti n ko omo pe iro pipa ko dara. “Oro rere ni n yo obi ni apo, oro buburu ni yo ofa l’apo.” Omo ni lati maa ni ohun rere lenu nitori oro enu eniyan lo n fi bi okan ati inu eni ti ri han. Omode ki i soro buburu lenu. Kaka bee o dara ki o maa woye. Omode gbodo mo igba to ye ki o soro ati igba ti o ye ki o dake. Gbogbo awon eko wonyi ni won sodo sinu eko ile.
(vi) Igboran: Igboran se pataki fun omode. Omode n ko bi a se n gboran si obi ati ebi lenu. Igboran ki i je ki omode sise. Awon agba ni “Aguntan ti o b aba ajar in dandan ni ki o je igbe”. Bee ni “A ki i pe ni lole ki a maa gbe omo ewure sere”. Imoran ni awon owe wonyi lati enu awon agba. Owe je ara ona ti awon Yoruba fi n ko omo ni eko ile. Omo ti o ba mu imoran agbo lo ni a n pe ni ologbon omo. “Omo ti a n ba wi to warunki, yoo parun ni ogan.” Oro agba ni.
(vii) Oninu-didun Olore: Bi omoluabi ni ohunkohun, inu re a maa dun lati fun elomiran ninu re. ohun to dara ni ki a maa se itore fun awon alaini ati arugbo.
Bi a se n ba eniyan gbe po ni irepo
- Ifarada: A ni lati ni ifarada ki a to le gbe ni irepo pelu awon eniyan ni awujo. A gbodo year fun ohun to je mo ikanra ati iwa igberaga.
- Imowa fun oniwa: Bi a ba n ba eniyan gbe po, a ni lati mo wi pe iwa wa ko le sokan. Tayewo ati Keyinde, ti won gbe inu kan naa fun osu mesan-an ko mu iwa kan naa waye. Lati wa ni irepo, a ni lati mo iwa fun oniwa.
- Suuru nini ni akoko wahala: A ko gbodo je ki wahala tan wan i suuru. ‘Suuru lere’ ni awon agba wi. Ti a ba le ni suuru, ipepo wa ni awujo ko ni soro.
- Yiyan ore to daralati ba rin: “Fi ore re han mi, ki n so iru eeyan ti o je. Ni awujo, a gbodo mo iru eni ti a o ba kegbe. Won ni “Agubtan to ba aja rin, a je igbe.” Egbe rere lo pe. Iru won ko ni si wahala, bee ni a o maa wan i irepo ninu ile ati ni ode.
- Ife: Won ni “Ife ni akoja ofin”. Ki a feran omolakeji ni ofin ti Olorun fun wa ni. Ti ife ba wa ninu ile, ikoriira, aso tenbelekun yoo di ohun afin-seyin ti eegun n fi aso.
- Ninu iberu Olorun: “Iberu Olorun ni ipinlese ogbon”. Bi a ba sun mo Olorun, ti a n ka oro re, ti oro re si n gbe inu eni, gbede bi o se n ro koko lehinkunle ni ibagbe wa pelu awon eniyan yoo ri. Bi a ba wa ninu Oluwa, ti Oluwa si n gbe inu wa, ko sewu loko, afi giiri aparo.
Awon ona bi a se n year fun iwa aito ni awujo
- Nipa titele imoran awon obi eni
- Mimo iru ore ti a oo bar in tabi lilodi si egbe buburu: aguntan to b aba ajar in yoo je igbe.
- Ki a maa tele ofin Orile-ede
- Nipa fifun ara eni ni ijanu nipa oro siso
- Nipa rerun ni ona to to nigbogbo igba
- Nipa titele ofin Olorun ti a gbo ninu iwaasu ati titeti si oro Olorun
- Rinrin ni awujo awon olododo.
Ise Amutilewa
- So ona marun-un ti a le gba huwa omoluabi
- So ona marun-un ti a fi le year fun iwa aito lawujo
See also
AKORI EKO: ATUNYEWO AAYAN OGBUFO
AKORI EKO: ORAN DIDA ATI IJIYA TI O TO
AKORI EKO: IYATO TI O WA LARIN ORO APONLE ATI APOLA APONLE