Asa isomoloruko je ona ti a n gba fun omo tuntun ni oruko ti yoo maa je titi lae ni ile Yoruba.
Gbogbo ohun ti olodumare da saye lo ni oruko. oniruuru ohun-elo tabi eronja ni Yoruba si maa n lo ni gba Ikomojade . Ojo kefa ni Yoruba n so omo loruko, I ba se omokurin tabi omobinrin tabi ibeji sugbon ni ibo miiran , ojo kesan-an ni won n so omokunrin lorunko, ojo keje ni ti obinrin ti awon ibeji ni ojo kejo.
Die lara ohun elo isomoloruko niyi,
Ohun elo | Iwure/adura |
Obi | Bibi lobi n biku danu, bibi lobi n baarun danu, obi a bi ibi aye re danu. |
Orogbo | Orogbo maa n gbo saye ni, o o gbo o, wa a to, wa a gbo kejekeje, o ko ni gbo igbo iya. |
Oyin | A kii foyin senu ka roju koko, oro bi oyin bi adun ko ni dagbere fun o o koni je ikoso laye. |
Oti | Oti kii ti, oko ni ti laye bee ni oti kii te, o ko ni t e |
Epo pupa | Epo ni iroju obe, aye re a roju. |
Iyo | Iyo nii mu obe dun, iwo ni o maa mu inu awon obi re dun. |
Ataare | Ataare kii bimo tire laabo, fofo ni le ataare n kun, oye re a kun fomo. |
Aadun | adun adun ni a n ba nile aadun, ibaje oni wole to o. |
Ireke | A kii ba kikan ninu ireke, ikoro ko ni wo aye re lae, aye re yoo dun |
Omi tutu | Omi la buwe, omi la bumu enikan kii ba omi sota,koo mu to
Ko ni gbodi ninu re o Ko si ni sa pa o lori……… |
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO ITAN AROSO – KIKA IW E TI IJOBA YAN
Igbelewon:
- Kin ni asa isomoloruko?
- Ko ohun elo isomoloruko marun un ki o si so bi a se n fi wure fun omo tuntun
- Ko onka lati aadota de ogoorun
Ise asetilewa:Ise sise inu Yoruba Akayege for jssone
See also
AKOLE ISE: BI ASA SE JEYO NINU EDE YORUBA
ONKA YORUBA LATI OOKAN DE AADOTA (1-50)
AKOLE ISE: LITIRESO ALOHUN TO JE MO ESIN