Aroko ni atinuda ero eni, ti a ko lori ori oro kan Pataki si inu iwe fun onkawe lati ka.
Orisi aroko ti o wa niyi;
- Aroko oni leta
- Aroko onisorogbesi
- Aroko alariyanyan
- Aroko alapejuwe
- Aroko ojemo – isipaya
- Aroko atonisona asotan
- Aroko oniroyin
Awon ilana to se Pataki fun aroko kiko
- Yiyan ori-oro: A ni lati fa ile tere si ebe ori-oro ti a n ko aroko le lori
- Sise ilepa ero: A ni lati ronu jinle ki a si to ero wa kale ni okookan ninu ipinro kookan
- Kiko aroko: Ifaara ko gbodo gun ju o si gbodo ba akoko mu.
- Ipinro: Akoto ode-oni se Pataki ni ipinro kookan bii afiwe, owe, akanlo ede abbl.
- ILO-EDE: Ojulowo ede se Pataki ninu aroko
- IGUNLE/IKADi: Eyi ni ipin afo ti o pari aroko o gbodo se akotan gbodo koko, ero ati ori oro ti a yan.
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: ISE ABINIBI ILE YORUBA
Ise abinibi/isenbeye ni ise iran ti a jogun lati owo awon baba nla wa.
Iran kookan ni o ni ise abinibi ti a mo ti o si f ease-file omo lowo. Yoruba lodi si iwa ole, lati kakore ni won si ti maa n ko awon omo won ni ise abinibi won. Ni geere ti a ba ti bimo ni awon obi re yoo ti da ifa akosejaye lati mo iru ise ti ele daa yan fun omo naa. Awon ise abinibi Yoruba niwonyi;
Awon ise isembaye Yoruba ni wonyi;
- Ise Agbe
- Ilu lilu
- Ikoko mimo
- eni hihun
- aro dida
- Ise ode
- Ise onidiri
- Ise akope
- Ise Alagbede
- Ise ona bii;
- Ona igi
- Ona okuta
- Ona awo
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: ITUPALE ASAYAN IWE LITIRESO APILEKO TI AJO WAEC /NECO YAN.
Igbelewon :
- Fun aroko ni oriki
- Ko orisi aroko mefa
- Salaye awon ilana ti alaroko yoo fi sokan bi o ba n ko aroko
- Kin ni ise isembaye/
- Ko awon ise isembaye ile Yoruba
Ise aetilewa: mu okan lara ise isembaye ile Yoruba ki o si salaye lekun-un-rere
See also
AKOLE ISE: SISE OUNJE AWUJO YORUBA
AKOLE ISE: ITESIWAJU LORI EKO IRO EDE