Aroko je ohun ti a ro ti a sise akosile.
Aroko alapejuwe ni aroko ti o man sapejuwe eniyan, ibikan ati nnkan to n sele gege bi a se ri i gan-an. Apeere:
- Oja ilu mi
- Egbon mi
- Ile-iwe mi
- Ouje ti mo feran
- Ilu mi abbl.
Aroko lori Ile-Iwe mi
Oruko Ile-eko mi ni Elias International School. O wa ni Ojule keji-Ikerin ,Opopona ile-Epo, Oke-odo, ipile Eko. Oludasile ile iwe mi ni Dokita Dosumu. ile-iwe mije ile oloke meta meta ti o fegbe kegbe ti a si fi ilekun onirin si enu ona abawole re.
A kun ile-iwe mi ni awo ewe gege bi aso ile iwe wa. Iyara ikawe fun kilaasi girama ati alakobere po jantirere bee ofisi awon oluko ati alase ile-iwe naa ko kere niye.
A ni yara ero ayara bi asa, yara imo sayensi, yara imo ede, yara ibi ikawe ati iyawe, yara ijeun.
A fi ododo se ile-iwe mi losoo bee. Leyin ile iwe mi, a ni papa isere fun awon ere idaraya bi boolu alafese gba, ere idije, boolu alafowo gba abbl.
Apapo awon omo-ile mi le ni oodunrun, awon oluko wa le ni aadota. Awon omo ile-iwe mi je omo gidi nitori won n ko wa ni eko-iwa, akojopo eko ile, bi a ti n huwa ni awujo ati eko bibeli.
Ti a ba n soro nipa awon oluko wa awon oluko wa dangajia, won ni oyaya, iwa pele, bee ni won mo bi a ti n ba awon obi se.
Opolopo obi feran ile-iwe mi pupo nitori pe ibe ni awon looko-looko ti o di ipo giga mu ni orile ede yii ti jade bee ni esin idanwo ase kegba wo ile eko giga ti yunifaasiti won maa n dara pupo. mo feran ile-iwe mi nitori pe,
- Awon oluko wa kun ojo osuwon
- O ni awon ero ikawe igbalode
- Agbegbe re dun-un kawe
- Won n ko ni bi ati n je omo rere ni ile ati fun orile ede lapapo
EKA ISE: ASA
AKOLE ISE: OYA JIJE ATI OHUN ELO OYE JIJE.
Bi a se n joye ni ilu kan yato si bi a se n joye ni ilu miran.
Makan –makan ni oye jije je ni ile Yoruba.
Oniruuru oye jije ni ile Yoruba.
- Oye Oba
- Oye Baale
- Oye Iyalode
- Oye Ajiroba
- Oye Bobajiro
- Oye Iyalaje
- Oye Afobaje
- Oye Majekobaje
- Oye Ile
- Oye Eleto
- Oye Baba-Isegun
- Oye Gbajumo. Abbl
Ohun elo Oye Jije
- Ewe oye
- Etutu lorisirisi
- Ileke owo, orun, ese
- Ade-oba
- Ilu lorisirisi
- Igba oye
- Irukere
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: AWON LITIRESO APILEKO-EWI
Ewi apileko litireso je ijinle oro ti o ku fun laakaye, ogbon ati oye ti a fi ona ede ati oro ijinle gbekele.
Awon koko ti a ni lati tele ti a ba n ko ewi apileko.
- Eni ti o ko ewi naa: mimo itan igbesi aye akewi
- Koko oro: onka-ewi gbodo mo koko ti ewi naa dale lori
- Eko ti ewi naa n ko wa se Pataki lati mo
- Ona ede ati asa ti o suyo: onkawe gbodo le toka asa Yoruba ati oniruuru ona ede bii, owe, akanlo ede, afiwe, asorege abbl.
Igbelewon:
- Kin ni aroko?
- Fun aroko atonisona asapejuwe loriki
- Ko apeere aroko asapejuwe meta
- Ko oniruuru oye jije ile Yoruba marunun ati ohun elo oye naa
- Fun ewi apileko litireso ni oriki
- Ko ilana kiko litireso naa
Ise asetilewa: ko aroko lori ounje ti o feran ju
See also
AWON LITIRESO APILEKO ERE-ONITAN
ORIKI ATI ILANA KIKO AROKO YORUBA PELU APEERE
AKOLE ISE: ASA ATI OHUN ELO ISOMOLORUKO