ALIFABEETI JE AKOJOPO LETA TI ASE AKOSILE RE GEGE BI IRO NINU EDE YORUBA.
ALIFABETI EDE YORUBA
Aa Bb Dd Ee Ee Ff Gg GB gb Hh Ii Jj Kk Ll Mm Nn Oo Oo Pp Rr Ss Ss Tt Uu Ww Yy
Apapo alifabeti ede Yoruba je meedogun (25)
Ona meji ni a le pin alifabeeti ede Yoruba si. Awon niyi;
Iro Konsonanti: Eyi ni iro ti a pe ni igba ti idiwo wa fun eemi.
Awon Konsonanti naa ni:
Bb Dd Ff Gg GB gb Hh Jj Kk Ll Mm Nn Pp Rr Ss Ss Tt Ww Yy
Apapo konsonanti ede Yoruba je mejidilogun (18)
Iro faweli: Eyi ni iro ti a pe nigba ti ko si idiwo fun eemi
Eyi pin si ona meji:
Iro faweli airanmupe: A kii ran mu pe iro yii rara bee ni ko si idiwo fun eemi tabi afefe ti a n pe.
Meje (7) ni iro faweli airanmupe
Aa Ee Ee Ii Oo Oo Uu
Iro faweli aranmupe: A maa n ran mu pe awon iro yii. Ni gba ti a ba n pe awon iro yii jade, eemi maan gba iho imu ati enu jade lee kan naa.
Marun-un (5) ni iro faweli aranmupe – an, en, in, on, un
Apapo iro faweli ede Yoruba je mejila (12)
Igbelewon:
- Kin ni alifabeeti ede Yoruba?
- Ona meloo ni a pin alifabeeti ede Yoruba si?
- Ko won sita
Ise asetilewa :ISE SISE NINU IWE ILEWO YORUBA AKAYEGE
EKA ISE ASA
AKOLE ISE Itan Isedale Yoruba
- Itan so pe ilu meka ni Yoruba ti wa
- Itan fi ye wa pe Lamurudu ni baba nla Yoruba
- Lamurudu je Ogbontegi abogipa
- Itan so pe awon elesin musulumi gbe ogun ti Lamurudu lati fi esin iborisa sile
- Itan fi ye wa pe inu ogun yii ni Lamurudu ku si
- Ba kan naa, itan so pe Lamurudu ni baba Oduduwa
- Leyin iku Lamurudu, Oduduwa ati awon eniyan re sa wa si ilu ile ife
- Ilu ile-ife ni o je orisun fun gbogbo ile Yoruba
- Oruko omo Oduduwa ni Okanbi
- Okanbi ti o je omo Oduduwa bi omo meje. Awon ni:
S/N | ORUKO | ILU TI WON TE DO SI | OGUN TI WON PIN |
A | Olowu | Owu | Aso |
B | Alaketu | Ketu | Ade |
D | Oba Ibini | Bini | Owo eyo |
E | Orangun | Ila | Iyewo |
E | Oni Sabe | Sabe | Eran Osu |
F | Onipopo | Popo | ILeke |
G | Oranmiyan | Oyo | Ile |
Igbelewon:
- Ni sisentele so itan isedale Yoruba
- Daruko awon omo Okanbi pelu ogun ti won pin leyin iku baba won
Ise asetilewa: ya maapu omo eya ile yoruba
EKA ISE: LITIRESO
AKOLE ISE: ORIKI LITIRESO.
Litireso ni akojopo ijinle oro ni ede kan tabi omiiran.
Litireso je ona ti Yoruba n gba fi ero inu won han nipa iriri won gbogbo.
Ona meji ni a le pin litireso si, awon ni
- Litireso alohun
- Litireso apileko
Litireso Alohun: Eyi ni litireso ti a fi ohun enu gbe jade ti a jogun lati odo awon baba nla wa.
Litireso alohun pin si;
- Ewi
- Oro geere
- Ere Onise.
Litireso Apileko: Eyi ni litireso ti a se akosile ni gba ti imo moo- ko – moo-ka de.
Litireso apileko pin si;
- Ewi apileko
- Ere Onitan
- Itan Oroso
Igbelewon:
- Fun litireso ni oriki
- Ona meloo ni a pin litireso ede Yoruba si
- Salaye lekun-un rere
Ise asetilewa: ko apeere ewi alohun Yoruba marun-un
See also
AKOLE ISE: KIKA IWE APILEKO TI IJOBA YAN
Akole ise: onka Yoruba (300-500)
Onka Yoruba (101 – 300)