Skip to content

Inu ede ti a ti n ya oro lo.

Ona ti a n gba ya oro wonu ede Yoruba.

 

Akoonu

Oro – ayalo -: ni awon oro ajeji ti a maa n ya wonu ede Yoruba lati inu ede miiran

Oro – ayalo -: ni mimu oro lati inu ede kan wo inu ede miiran lona ti pipe ati kiko re yoo fi wa ni ibamu pelu ede ti a mu-un wo.

Oro – ayalo maa n mu ki ede dagba.

Bakan naa, o maa n je ki oruko wa fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba n sese n wo awujo wa

 

Yoruba ni ilana meji ti won n gba ya oro wo inu ede Yoruba, awon naa ni

–         Ilana afetiya

–         ilana afojuya

Ilana afetiya -: eyi ni pipe oro ayalo ni ona to sunmo bi awon elede se n pe oro gan-an

 

Bible –             Baibu

Peter    –           Pita

Table   –           Tebu

Esther –                        Esita

Deacon –          Dikin

Council –         kansu

Al- basal –        alubosa

 

Ilana afojuya :- eyi ni kiko oro ni liana eyi to sunmo bi awon elede se n ko.awon elede se n saaba maa n lo ilana yii

 

Soldier             –          soja

Table              –           tabili

Peter                –           peteru

Esther             –           esiteri

Bible                –           Bibeli

Deacon            –           Diakoni

Paradise           –           paradise

Hebrew           –           Heberu

 

Inu awon ede wonyii ni a ti n ya oro wo inu ede Yoruba

Ede  Geesi

Ede  Larubawa

Ede  Faranse

 

Bi oro ayalo se wonu ede Yoruba

Eyi ni orisirisii ona ti oro ayalo gba wonu ede Yoruba

  1. Esin:- nipase esin musulumi ati esin Kristi ti won mu wa fun wa ni a se ni awon oro wonyi:  mosalasi, soosi, alijanna, angeli bibeli, pasito, kurani abbl
  2. Ajose owo:- eyi ni ajose owo laarin Yoruba ati awon eya miiran ap: senji, korensi, wisiki, buluu
  • Eto iselu:- Nipase ijoba ajeji ti awon larubawa ati Geesi mu wa ni a ti ya opolopo oro bii seria, kootu, sinato
  1. Asa ati olaju:- ajumose nipa asa ati olaju mu ki a ya opolopo oro lo ap: yigi, marede
  2. Eto eko:- eyi ni oro ti a ya nipa eto eko ap tisa, boodu,

 

AWON IRO TI A FI N SE AARO ARA WON

Ki oro ede Geesi ti a ya lo to le di ara oro mu ede Yoruba, o gbodo tele ofin ede Yoruba

  1. Konsonanti ki i gbeyin oro ninu  ede Yoruba bi oro ayalo ba ni, a o fi faweli ti o ye seyin re, o le je: i, u   a tabi o, ap

Bread – buredi

Gum – goomu

Bed – beedi

Shirt – seeti

fail – feeli

Glass – gilaasi

Gold – goolu

 

  1. Yiyo konsonanti ipari oro ayalo kuro ap

Mobil – mobi

Moses – mose

Jesus – jesu

Lazarus – lasaru

 

iii.        Yiya isupo konsonanti oro- ayalo fifi faweli ya isupo konsonanti ap

bread – buredi

milk – miliiki

iray – Tiree

station – Tesan

belt – beliiti

 

  1. Ifiropo konsonanti ninu oro ayalo Nigba miirran konsonanti oro Geesi maa n yato si ti Yoruba ap:

Lazarus – lasaru

Church – soosi

Queen – kun-yin

Valve – faafu

Stamp – sitanbu

Cup – koobu

 

  • Ami gbodo wa lori oro- ayalo
  • Oro ayalo lo maa n bere pelu ami ohun oke
  • Faweli aranmupe maa n bere oro ayalo
  • Iwulo oro ayalo
  • Oro ayalo lo maa n mu ki edi dagba
  • Nipa yiya oro lo a maa n ri oruko fun awon nnkan ati ero tuntun ti o ba sese n wo awujo wa.

Ofin ti o de oro ayalo

 

IGBELEWON

  1. Kin ni oro-ayalo?

Ona meloo ni a n gba lati ya oro lo? Salaye won pelu apeere

 

IWE AKATILEWA

Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.

 

ASA

AWON ISERUN ENI

Akoonu

Awon iserun  eni tumo si baba-nla eni, ti o se iran eni sile tabi ori eni ti iran kan ti bere. Ko si iran kan ni ile Yoruba ti ko ni awon ti o see nitori pe ‘okun ki i gun titi ki o ma ni ibi ti o ti fa wa.

Awon baba-nla wa ti a n toka si yii ti wa nigba iwase, won ti se gudugudu meje ohun yaaya mefa nigba aye  won.

Awon Yoruba gbagbo pe odo ki san ki o gbagbe orisun re, opolopo igba ni won maa n pe oruko baba-nla  fun iyonu  ati aabo nitori pe won gbagbo pe eni to ba ti ku ni agbara nla lati bukun  awon ti won je iran won ni aye.

Akoko odun tabi loorekoore ni a maa n se etutu lati tu awon iserun eni loju fun oore ti won n reti lodo won.

Odoodun ni awon iran miiran maa n bo iserun won tabi nigba ti wahala tabi idarudapo ba wa ninu ebi won.

 

Ebi kookan ni o ni ojubo ti won ti n bo iserun won, o le je agboole tabi ni eyin odi ilu. Iru eyin odi yii le je ibi ti baba-nla won tedo si nigba  iwase.

 

Ogangan ibi ti oku ba kori si ni won ti n se etutu

Orisiirisii ohun jije mimu ni won n bo iserun eni, agbo tabi agutan adie abbl. Won yoo si  ro eje re si oju oori iserun won naa, won yoo da obi, ti o ba si ti yan, o ti  gba niyen, akoko ayeye  ni o maa n je fun gbogbo ebi

 

Ni ile Ijebu Agemo ni  won nse. Awon ni ipinle Eko kii fi Adamu – Orisa sere.

Ila oju, oriki –orile ati isesi iran kookan je eyi ti a fi n da ara wa mo, ti o si n mu iserun eni wa si iranti.

 

Inu oriki-orile ise, ise, iwa, esin, ati eewo iran ni a ti n gbo oniruuru oruko ti an baba-nla wa ti je seyin.

Ap

 

Iran onikoyi je iran jagun, eyi si han ninu oriki ati itan iran won, baba –nla won je jagunjagun.

Iwa akin hihu ko si fi iran yii sile. Iran aagberi ko fe gbagbe oogun abenu gongo.

Iran Olofa kan o je gbagbe ijakadi.

 

IGBELEWON

  1. Ki ni iserun eni tumo si?
  2. Daruko awon iserun ile Yoruba ti o mo.

 

IWE AKATILEWA

Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.

 

ETO EBI

Ni ile Yoruba, ebi ni a tun n pe ni alajobi tabi molebi. Alajobi ni iya, baba, egbon, aburo ati ibatan eni ni apapo. Eto ebi ni opomulero ti o gbe asa, ise, ati ibara-eni-gbepo awon Yoruba duro. omo nibi-niran ni awon Yoruba. Bi won se tan si ile baba ni won tan si ile iya.

 

Eto ebi bere lati inu ile. Gege bi asa baba ni olori ile, iya ni atele ki o kan awon omo gege bi ojo ori won. Iko kokan ni o ni ipa ti o n ko lati mu ki ife, isokan, laafia ati ajosepo wa ninu ebi.

 

Lara awon ibasepo ti o wa ninu ebi ni:

Ise obi si omo

Ise omo si obi.

Ibasepo laarin omo iya si omo iya

Ibasepo laarin Obakan si Obakan

Ibasepo laarin idile eni ati baba eni

Ipo Baale ati ojuse re

Ipo Iyaale Ile ati ise re

Ipo Obinrin ile

Ipo Orogun

Ipo Omo Osu ati ise won

Ipo Omokunrin Ile ati ise won

Ipo Omobinrin ile

Awon Alejo tabi Alabagbe

 

IGBELEWON

  1. Salaye awon wonyi: Obakan, Iyekan-eni, Omo Osu, Obinrin Ile ati Omobinrin Ile.
  2. Ki ni ojuse Baale Ile? Salaye ni kikun.

 

IWE AKATILEWA

Aewoyin S.Y (2009) IMO, EDE, ASA ati LITIRESO YORUBA S.S.3 Copromutt Publishers.

 

LITIRESO

Kika iwe ti ajo WAEC yan

IGBELEWON

  1. a. Kin ni iserun eni?
  2. Igba wo ni a n bo iserun eni?
  3. Kin ni a fi n bo won?

 

IWE AKATILEWA

Imo Ede Asa ati Litireso Yoruba  (SS3)  S.Y  Adewoyin 277 – 279

 

APAPO IGBELEWON

  1. Kin ni oro-ayalo?
  2. Ona meloo ni a n gba lati ya oro lo? Salaye won pelu apeere
  3. Salaye awon wonyi: Obakan, Iyekan-eni, Omo Osu, Obinrin Ile ati Omobinrin Ile.
  4. Ki ni ojuse Baale Ile? Salaye ni kikun.

 

ATUNYEWO EKO

  1. Ki ni oro oruko?
  2. Ki ni oro aropo oruko?
  3. Ko iyato merin laarin oro oruko ati oro aropo oruko.

 

ISE ASETILEWA

  1. Awon Iserun eni tumo si (a) Baba-nla eni (b) eni ti o se iran eni sile (d) eni to na omokunrin ile
  2. Inu _______ ni a ti n gbo nipa oniruuru oruko idile (a) oriki orile (b) iwure (d) ofo
  3. Ojubo iserun eni le wa ni _____ ati (a) Inui le (b)agboole (d) ilu odikeji
  4. Ona _____________ ni a le gba ya oro lo ninu ed Yoruba (a) meji (b) meta (d) merin
  5. A ya pasito ni pase _____(a) esin (b) eto eko (d) imo ero

 

APA KEJI

  1. Kin ni oro – ayalo?
  2. Ona meloo ni a n gba ya oro wonu ede Yoruba
  3. Ko irisi awon oro Geesi wonyi sile leyin igba ti a ba ti ya won wonu ede Yoruba

Teacher, Starch, Milk, bread, class, scale, block, trouser, brother, shilling

  1. Kin ni iserun eni
  2. Daruko apeere Iserun eni meta nile Yoruba
  3. Daruko igba ati ohun ti a si n bo iserun eni.
  4. Salaye eto ebi ni kikun.

 

See also

FONOLOJI EDE YORUBA

ASA ELEGBEJEGBE

SILEBU EDE YORUBA

AKOLE ISE: ISORI ORO NINU GBOLOHUN

AKOLE ISE: AROKO ATONISONA ALAPEJUWE

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *